HYMN 709

1. A dupe Oluwa 

   F‘ajodun oni

   O da emi wa si 

   Ogo f’oko Re 

   Pelu orin ayo 

   L'a o fi josin

   Fun bukun aye wa 

   On reti orun. 

Egbe: Ajodun de, e yo

     Ke, AIeluya

     A m 'ore ope wa

     Tewo gb’ore wa.


2. Opo l'elegbe wa 

   Ni ko tun si mo 

   Opo ti sako lo 

   Kuro lodo Krist 

   A dupe Oluwa 

   Pe O da wa si

   O si tun ka wa ye 

   F’ajodun oni. 

Egbe: Ajodun de, e yo...


3. Baba wa li orun 

   Awa se pinu

   Pe ao sin Jesu 

   L'ojo aye wa

   A o sise fun dagba 

   Soke ijo wa

   Tit‘ ao fi je ‘pe Re 

   Fun ‘simi orun. 

Egbe: Ajodun de, e yo...


4. Wo Oluw'ajodun 

   A f’ope fun O

   Je k’ire ajodun 

   kari gbogbo wa 

   A be O, Olorun

   Fun wa l’agbara

   Lati sin O d'opin 

   Ojo aye wa.

Egbe: Ajodun de, e yo

     Ke, AIeluya

     A m 'ore ope wa

     Tewo gb’ore wa. Amin

English »

Update Hymn