HYMN 710

Tune: D 6s


1. OGO, iyin, ola

   Fun Olugbala wa 

   T’o da eni wa si 

   Titi d'ojo oni

   Ayo kun okan wa 

   Fun anfani nla yi 
 
   Lati sise fun O 

   N’nu ogba re laye.


2. A dupe fun toni

   On agbara t'erni 

   At’ebun ife nla

   Ti o fi so wa po 

  Olusagutan wa 

  Tewo gba iyin wa 

  Nitori anu Re 

  Se wa l’okan laelae.


3. Bukun wa, Oluwa 

   Loni ajodun wa

   Ran ami Re si wa 

   K’a layo n'nu sin Re 

   Ka si s'aseyori

   N’nu ise isin wa 

   K’a si fi Jesu se 

   Igbekele wa lae.


4. Eleda, Oluwa

   Orisun gbala wa 

   Se wa ye f’ajodun

   Ti ibugbe loke

   N‘ipari ajo wa

   N’nu aye osi yi

   K'a le ni ibugbe

   Lodo Re Oluwa. Amin

English »

Update Hymn