HYMN 711

(FE 738)
"Tani ki ba beru Re, Iwo Oba 
orile-ede" - Jer. 10:7
Tune: Lo kede ayo na fun gbogbo aiye1. E ku ewu odun, E ku ‘yedun 

   A s’ope fun Olorun wa,

   T’o mu wa ri ajodun oni yi 

   Ni orile aiye.

Egbe: Awa dupe a run ope da 

     Ogo, Ola at'Agbara ati'pa 

     F'Od'agutan t'o gunwa.


2. Kristi se ‘mole at'alabo wa 

   M'ese agbo Re yi duro 

   Pese ise f’awon ti ko ri se 

   Se ‘wosan alaisan.

Egbe: Awa dupe...


3. Oluwa ni Olus’Agutan mi

   Emi ki yio se alaini

   O mu mi dubule ni papa oko tutu 

   O tu okan mi l'ara.

Egbe: Awa dupe...


4. Bi emi ba tile nrin koja lo 

   Larin afonifoju 'ku

   Emi ki o si beru ibi kan 

   Tori ‘Wo wa pelu mi.

Egbe: Awa dupe...


5. Awon ogo Re ati opa Re 

   Awon ni o tu mi ninu

  O te tabil’ onje sile n’iwaju 

  L’oju awon ota mi.

Egbe: Awa dupe...


6. Iwo da ororo si mi l’ori

   Ago mi k’ akun wo sile

   Ire, anu ni yio ma to mi lehin 

   L’ojo aiye mi gbogbo.

Egbe: Awa dupe...


7. Kristi Olugbala awa mbe O 

   Jowo ran Emi Re si wa

   K’a le wo wa l’aso Ogo didan 

   Ni ikehin ojo aiye wa.

Egbe: Awa dupe...


8. Kabiyesi, Oba Alaiyeluwa 

   Metalokan Aiyeraiye

   Fun wa n’isegun n’igba idanwo 

   K’owo esu ma te wa.

Egbe: Awa dupe...


9. Baba oke orun awa mbe O 

   Sure fun wa k’a wa to lo 

   Jesu bebe fun awa omo Re 

   K’a le j’oba pelu Re.

Egbe: Awa dupe a run ope da 

     Ogo, Ola at'Agbara ati'pa 

     F'Od'agutan t'o gunwa. Amin

English »

Update Hymn