HYMN 712

t.H.C 366 8s 7s (FE 739)
“E wa wo awon ise Oluwa" - Ps. 46:8
Tune: s.s.l.s.d.d.I.s.d.m.d.s.m.r:‐1. EGBE Kerubu to jade 

   Awa lo ns’ajodun wa

   K’ogun orun ba wa gberin 

   K’araiye gbohun soke.

Egbe: Halleluya, Halleluya

     T'ewe t’agba ko gbe rin - 2ce


2. Ope lo ye f’Olugbala

   Fun idasi wa oni

   Ota ka wa nibi gbogbo 

   Sugbon Jesu ko wa yo.

Egbe: Halleluya, Halleluya...


3. Emi Mimo ko pelu wa 

   L’okunrin at’lobinrin 

   kerubu pelu Serafu

   K’a pade n’ijo t’orun.

Egbe: Halleluya, Halleluya...


4. Olorun Olodumare

   Obangiji Oba wa

   Ma je k’ebi ale pa wa 

   K’enikeni ma pose.

Egbe: Halleluya, Halleluya...


5. Kerubu pelu ogun re

   Ni awon ariran nri

   Holy Maikeli pelu ‘da Re

   O ngesin po yi wa ka.

Egbe: Halleluya, Halleluya...


6. Abo Oluwa Onike

   L’awa Egbe bora mo

   Ko s’ohun ibi to le se wa 

   Lagbara Metalokan.

Egbe: Halleluya, Halleluya...


7. Eni l‘oyun a bimo la

   Agan a f’owo bosun

   Olomo ko ni padanu

   Iku ko ni ri wa gbe se.

Egbe: Halleluya, Halleluya...


8. Gbogbo awon ti ko ri se 

   L'okunrin l'obinrin

   Ipese Olodumare 

   Awamaridi lo je.

Egbe: Halleluya, Halleluya...


9. E wa ba wa k’Alleluya 

   F’odun miran Kerubu 

   T’Oluwa d'egbe na sile

   Iarin Egbe Serafu.

Egbe: Halleluya, Halleluya...


10. Oba aw’Egbe Kerubu

    Jesu Kristi Oluwa,

    Awa nkorin, awa si nyo

   Ogo fun Od’agutan.

Egbe: Halleluya, Halleluya

     T'ewe t’agba ko gbe rin

     T'ewe t’agba ko gbe rin. Amin

English »

Update Hymn