HYMN 714

(Fe 741)
“Enyin ti gba Emi isodomo" - Rom.8:15
Tune: Baba jo ranti mi1. ISODOMO akoko 

   Jesu Olugbala 

   Isodomo ikehin 

   Mose Orimolade.

Egbe: Ngo fo, ngo fo bayi 

     Ngo yo, ngo sese 

     Ngo korin Angeli 

     Halleluya Ogo.


2. Kini se t’e nyo bayi 

   Pelu mope owo nyin 

   Awa ri Jesu loni

   Ati Olorun Baba. 

Egbe: Ngo fo, ngo fo bayi...


3. Kerubu, Serafu aiye 

   Ayo lo po to bayi

   Aso funfun Ade Ogo 

   Jesu ti fi fun wa. 

Egbe: Ngo fo, ngo fo bayi...


4. Jesu ko oruko siwaju wa 

   Oruko ti Baba Re 

   Oruko t’Angeli ko mo

   A f’awa t‘a fifun.

Egbe: Ngo fo, ngo fo bayi...


5. A o ba Jesu joba

   Ni Egberun odun 

   Lehin na a o joba

   Aiye ainipekun. 

Egbe: Ngo fo, ngo fo bayi...


6. A ki Oloye meta

   E ku ori ire

   At’ agbagba Obinrin

   lru eyi s’oju emi wa.

Egbe: Ngo fo, ngo fo bayi 

     Ngo yo, ngo sese 

     Ngo korin Angeli 

     Halleluya Ogo. Amin

English »

Update Hymn