HYMN 716

1. GBO ohun Jesu ti nke pe 

   Tani y‘o sise loni

   Oko pon pupo fun ‘kore 

   Tani y’o lo ko wa l’e 

   Kikan kikan l’Oluwa npe 

   Ebun nla ni y’O fun o

   Tani y’o fl ayo dahun 

   Pe” Emi ni yi ran mi?


2. B’iwo ko le okun lo 

   Lati w’awon keferi

   O le ri won nitosi re 

   Nwon wa l’enu ona 

   B’o ko le fi wura tore 

   Ebun miran ko kere 

   Die t’o sise fun Jesu 

   ‘Yebiye ni l'oju Re.


3. B’iwo ko le se alore 

   L‘ori odi Sioni

   Lati t’oka s’ona orun 

   Lati f’iye lo eda

   Wole f'adura at’ore 

   Se ohun t’Olorun wi 

   Wo le se gegebi Aaron

   T’o gbowo woli soke.


4. Ma je k’a gbo ki o wipe 

   Ko si nkan t’emi le se 

   Nigbat’ emi eniyan nku 

   Ti Oluwa si npe o

   F’ayo gba ise t’O ran o, 

   Fise Re se ayo re

   Gbat’ o npe o, tara dahun 

   Pe emi ni yi, ran mi. Amin

English »

Update Hymn