HYMN 717

Tune: D 8s 7s or 8s 7s1. OLUSO-AGUTAN to wa

   Awa fe itoju Re

   Fun wa ni ibukun t'a nfe

   Si pese aye fun wa

   Jesu mimo, Jesu mimo)

   O ra wa, Tire ni wa) - 2ce


2. Tire ni wa fi wa s'ore 

   Ma se amona fun wa 

   Gba agbo Re lowo ese 

   Wa wa gbat'a sina

   Jesu mimo, Jesu mimo)

   Gbo ti wa, gba t‘a mbebe) - 2ce


3. Wo ti leri lati gba wa 

   B'a tile je elese

   Anu, ore agbara Re

   To fun dande elese 

   Jesu mimo, Jesu mimo)

   Je ka tete ro mo o) - 2ce


4. Je k'a tete wa oju Re

   Je k’a tete se ‘fe Re 

   Oluwa at'Olugbala

   Fi 'fe Re kun ok okan wa 

   Jesu mimo, Jesu mimo)

   Olufe, ma fe wa si) - 2ce Amin

English »

Update Hymn