HYMN 72

(FE 89)
"Oluwa mo awon ti se Tire" - II Tim. 1:191. OBA awon eni Mimo

   T'o mo ye awon ‘rawo

   Opo enit' Eda gbagbe

   Wa yika ite Re lati,

Egbe: Mimo Mimo, Mimo Mimo, Mimo Mimo

      Lo ye O.

      Iwo I'a ba ma f' iyin fun

      Olorun, Edumare.


2. Enit' o wa ninu ‘mole

   T oju enikan ko ri

   Mose ri akehinsi Re

   Oju Mose ran b'orun.

Egbe: Mimo Mimo...


3. Mole ti ‘kuku aiye bo

   Ntan mole roro loke

   Nwon je omo alade l'orun

   Eda gbagbe won t‘aiye.

Egbe: Mimo Mimo...


4. Lala at'iya won fun O,

   Eda ko rohin re mo

   Iwa rere won farasin

   Oluwa nikan lo mo

Egbe: Mimo Mimo...


5. Nwon farasin fun wa sugbon

   A ko-won s'iwe iye

   lgbagbo, adura, suru

   Lala on’jakadi won

Egbe: Mimo Mimo...


6. Nwon mo isura Re lohun

   Ka wa mo won Oluwa

   Nigba’O ba nsiro oso

   Ti mbe lara ade Re.

Egbe: Mimo Mimo...


7. E wole f’Oba Ologo

   Serafu e wole fun

   Niwaju ite Jehovah

   Olorun Metalokan.

Egbe: Mimo Mimo...


8. E wole f’Oba Ologo

   Kerubu e wole fun

   Niwaju ite Jehovah

   Olorun Metalokan.

Egbe: Mimo Mimo... Amin

English »

Update Hymn