HYMN 720

7s 6s (FE 747)
"Awa ri ohun abami Ioni" - Luku. 5:26
Tune: Gbekele Onigbagbo1. OJO ayo l‘eyi je 

   Awa ns'ajodun wa 

   Kerubu npe Serafu

   E jade wa woran.

Egbe: Halleluyah! korin kikan soke

     Halleluyah! f'Oba Olorun wa.


2. Egbe ogun orun nki wa 

   Pe mase jafara

   Akoko die lo ku 

  T’aiye y’o koja Io.

Egbe: Halleluyah!...


3. Ohun iyanu l’eyi 

   Nipa ti Egbe na 

   Nigbat’ igbagbo ti se 

   A ko ri iru eyi ri.

Egbe: Halleluyah!...


4. Gbogb’ awon alailera 

   T’o wa nin’Egbe na 

   Okunrin at‘Obinrin 

   Njeri si eyi na.

Egbe: Halleluyah!...


5. Won to wa nigberiko 

   Njeri si otito

   Pe aje ko n‘ipa mo 

   'Nu egbe Serafu.

Egbe: Halleluyah!...


6. Awon t’o wa n‘idale 

   Nwon nsope, nwon si njo 

   Soponna ko n'ipa mo

   ‘Nu egbe kerubu.

Egbe: Halleluyah!...


7. Serafu ma gbode kan 

   Ko si ‘ru eyi ri

   Kerubu ma gbode kan 

   Nwon nji oku dide.

Egbe: Halleluyah!...


8. Ogo ni fun Baba l’oke 

   Ogo ni fun Omo

   Ogo ni fun Emi Mimo 

   Metalokan lailai.

Egbe: Halleluyah! korin kikan soke

     Halleluyah! f'Oba Olorun wa. Amin

English »

Update Hymn