HYMN 721

(FE 748)
"Alaye alaye on ni yima yin O” - Isa.38:19 
Tune: Ibase p’Oluwa (K & S 82)1. OJO nla l‘eyi je

   T’a nse Ajodun wa 
 
   Kerubu.., e ho ye 

   Serafu, e gberin. 

Egbe: Halleluyah, Halleluyah 

      S’Oba wa

      Eniti o da wa si

      LAti tun ri odun yi 

      Ogo f’oruko Re.


2. Orun pe l’Osupa

   E fi ayo nyin han

   F’emi wa to d’oni

   Larin Egbe Kerubu.

Egbe: Halleluyah, Halleluyah... 


3. Sure fun wa loni

   Baba Mimo t‘orun

   Ma je ki a rahun 

   Nikehin aiye wa.

Egbe: Halleluyah, Halleluyah... 


4. lru Egbe Seraf‘ 

   Larin Ilu Afrika

   Igba wa sunmole

   T'ao bo l’oko eru.

Egbe: Halleluyah, Halleluyah... 


5. A dupe, Oluwa

   Fun Ajodun oni

   T’o s'oju emi wa

  Lori ‘le alaye.

Egbe: Halleluyah, Halleluyah... 


6. Ajodun nla kan mbe

   T'a o se loke Orun 

   Pelu awon Mimo

   Fun iyin Oluwa.

Egbe: Halleluyah, Halleluyah... 


7. A dupe, Oluwa

   Pe O ti gbo tiwa

   Ma jek‘a d’ese mo

   K‘a l‘ayo nikehin.

Egbe: Halleluyah, Halleluyah 

      S’Oba wa

      Eniti o da wa si

      LAti tun ri odun yi 

      Ogo f’oruko Re. Amin

English »

Update Hymn