HYMN 722

H.C 2nd Ed. 449 t.S. 65
P.M. (FE 749)
"E fi ope fun Oluwa” - Ps.105:1 
Tune: Ojo nla lojo ti mo yan1. OLORUN Olodumare

   A dupe fun 'dasi oni 

   Ajodun yi si tun ba wa 

   Ni ori ile agbaiye.

Egbe: A s'ope, a s'ope

       Fun idasi wa l'odun yi 

       Larin ota, larin egan 

       Larin awon oninubini 

       A s'ope, a s'ope

       Fun idasi wa l'odun yi.


2. Ajodun oni ko ba wa

   Ha! ayo t'orun ko d'opin 

   Egbe t'o t'orun sokale 

   Iru eyi ko si laiye.

Egbe: A s'ope, a s'ope...


3. Okunrin ati Obirin 

   E mura k'e d‘amure nyin

   Omode at'agbalagba

   Ki gbogbo wa korin s’oke.

Egbe: A s'ope, a s'ope...


4. Aje, Oso, Alawirin 

   Sanponno, Ologun ika 

   Igunnu at’awon elegun 

   Ko n’ipa kan lor‘Egbe na. 

Egbe: A s'ope, a s'ope...


5. Nigbat‘ Egbe yi ko bere 

   Awon kan nreti eleya 

   Nwon sebi egbe lasan ni 

   Nwon ko mo ise Olorun.

Egbe: A s'ope, a s'ope...


6. Metalokan l’Olorun wa

   Olorun ti ko n’ipekun

   Baba, Omo, Emi Mimo 

   Gbogbo won lo nsise won po.

Egbe: A s'ope, a s'ope

       Fun idasi wa l'odun yi 

       Larin ota, larin egan 

       Larin awon oninubini 

       A s'ope, a s'ope

       Fun idasi wa l'odun yi. Amin

English »

Update Hymn