HYMN 723

8.7.8.7.4.7
Tune: Ma toju mi Jihofah Nla1. OGO fun Olorun Baba 

   Ogo f’Olorun Omo 

   Ogo fun Olorun Emi 

   Jehofa, Metalokan 

   Ogo, Ogo

   B’ayeraye ti nkoja.


2. Ogo fun Eni t’o fe wa

   T‘o we abawon wa nu 

   Ogo fun Eni t’o ra wa

   T’o mu wa ba On j’Oba 

   Ogo, ogo

   Fun Od’agutan t’a pa.


3. ’Ogo, bukun, iyin laelae 

   L’awon ogun orun nko 

   'Ola, oro, ipa, ‘joba! 

   L’awon eda fi nyin I, 

   Ogo, ogo,

   Fun Oba awon Oba. Amin

English »

Update Hymn