HYMN 729

(FE 755)
"Gba wa Olorun igbala wa" - Kro.16:351. E dide omo-ogun gbala 

   Gbe oruko Jesu ga

   Fun ojo nla t’a ri loni

   Ti Maikeli Balogun wa.

Egbe: Maikeli Mimo Balogun 

      Maikeli Mimo Balogun 

      S’amona Egbe wa d'opin 

      B’awa segun Lusifa.


2. A dupe pe o je tiwa 

   Larin Egbe Serafu

   Ko si b’esu tile gb’ogun 

   Maikeli a bori won.

Egbe: Maikeli Mimo...


3. L’ojo na t’ogun gb’orun kan 

   Orun, aiye wariri

   lberu nla l'o gb’aiye kan 

   Maikiel f’oko e g’esu.

Egbe: Maikeli Mimo...


4. Mo gb’ohun na lati orun wa 

   Pe egbe ni fun aiye

   A le olufisun s’aiye

   Awon ayanfe yio la.

Egbe: Maikeli Mimo...


5. Egbe Kerubu ma beru 

   Pe Maikeli je tiwa

   Oso, aje ko n’ipa mo

   Lori Egbe Mimo yi.

Egbe: Maikeli Mimo...


6. Jesu, Omo Mimo Baba

   A f;ogo f'Oruko Re 

   Pe Maikeli ti segun esu 

   Awon ogun esu fo.

Egbe: Maikeli Mimo...


7. Gbati pe ‘kehin ba si dun 

   Olorun awa mbe O

   Ma jek’ owo esu te wa

   K‘a si le gb'ade iye.

Egbe: Maikeli Mimo Balogun 

      Maikeli Mimo Balogun 

      S’amona Egbe wa d'opin 

      B’awa segun Lusifa. Amin

English »

Update Hymn