HYMN 73

APA KINI H.C. 1 P.M (FE 90)
"Mimo Mimo Mimo Olodumare"
- Ifi. 4:8



1.  Mimo, Mimo, Mimo Olodumare,

     Ni kutukutu ni ‘wo o gbo orin wa,

     Mimo, Mimo, Mimo! Oniyonu julo,

     Ologo meta lai Olubukun.


2.  Mimo, Mimo, Mimo awon t'orun nyin

     Nwon nfi ade wura won lele y'ite ka,

     Kerubim Serafim nwole niwaju Re,

     Wo to ti wa to si wa titi lai.


3.  Mimo, Mimo, Mimo, Olodumare

     Bi oju elese ko le ri Ogo Re,

     lwo nikan lo mo ko tun si elomi

     Pipe 'nu agbara ati n'ife.


4.  Mimo, Mimo, Mimo Olodumare,

     Gbogbo ise Re n'ile l‘oke lo nyin O,

     Mimo, Mimo, Mimo Oniyonu julo

     Ologo meta lai Olubukun.  Amin

English »

Update Hymn