HYMN 732

(FE 758)
“E mase gba ore-ofe Olorun lasan"
 - 2Kor. 6
Tune: Oluwa Olorun gba wa1. BABA Aladura mura 

   Lati pade Kerubu 

   Jesu lo pe o, lo yan o 

   Lati d’Egbe yi sile

   O si pe gbogbo aiye lati wo

   ‘ko ‘gbala yi

   B’ojo wa ti nkoja lo. 

Egbe: Ojo nlo, ojo nlo - 2ce 

     Ise po t’awa o se 

     B’ojo wa ti nkoja lo.


2. Egbe Aladura mura 

   Lati pade Kerubu

   E ma je k’amure nyin tu 

   Lati pade Kerubu

   Gbe Ida ‘segun s’oke 

   Iye s’Olorun Daniel 

   Alleluyah! Jesu mbo 

   B’ojo wa ti nkoja lo.

Egbe: Ojo nlo, ojo nlo...


3. Olorun Metalokan wa, 

   Lati gbo adura wa 

   Jesu Olugbala Oba 

   Jowo gb’ebo ope wa 

   Emi Mimo sokale

   F’ore-ofe ba wa gbe 

   Ise po t’awa o se 

   B’ojo wa ti nkoja lo.

Egbe: Ojo nlo, ojo nlo...


4. Okun fe so gbogbo wa po 

   B’ojo wa ti nkoja lo 

   Kankan lao fa won s’agbo Re 

   B’ojo wa ti nkoja lo

   Sugbon eso oro Re 

   Ndagba l’osan at’oru 

   Gb’awon to subu dide 

   B’ojo wa ti nkoja lo.

Egbe: Ojo nlo, ojo nlo - 2ce 

     Ise po t’awa o se 

     B’ojo wa ti nkoja lo. Amin

English »

Update Hymn