HYMN 737

(FE 763)
“E lo e ma ko orile ede gbogbo”
- Matt.28:19 
Tune: Ohun Orin Awon Ilaje1. GBOGBO aiye Serafu de 

   Lati kede oro na 

   T’Olugbala ti fi lele 

   Lowo Orimolade.

Egbe: Lodo Baba Aladura 

     Eni to d'egbe yi sile 

     Nibi Serafu, Kerubu 

     Nyin Baba Mimo logo.


2. Adahunse, ateyepe

   Aye Egbe si sile 

   K’enyin wa ronupiwada 

   Lodo orimolade.

Egbe: Lodo Baba...


3. Babalawo, onitira

   E wa ronupiwada

   Ke wa di opo iye Re mu 

   Lodo Orimolade.

Egbe: Lodo Baba...


4. Sonponna ko lo sora re 

   Lodo Egbe Serafu 

   Oniwunde ti sokale 

   Sinu Egbe Kerubu.

Egbe: Lodo Baba...


5. Egungun ati gelede 

   E wa ronupiwada 

   Ka jumo yin Olorun wa 

   Ninu Egbe Serafu.

Egbe: Lodo Baba...


6. lgunnu ati agemo

   E wa ronupiwada 

   K'e wa di opo iye mu 

   Lodo Orimolade.

Egbe: Lodo Baba...


7. A juba Olorun baba 

   Omo at‘Emi Mimo 

   Metalokan aiyeraiye 

   Ninu Egbe Serafu.

Egbe: Lodo Baba...


8. Kerubu ati Serafu

   T'o wa ni gbogbo aiye 

   K’awa damure wa giri 

   Lati kdede oro na.

Egbe: Lodo Baba...


9. A ki Baba Aladura 

  T'Olorun f'Egbe yi ran

  Jerusalemu sokale 

  Lodo Orimolade. 

Egbe: Lodo Baba...


10. Enyin ara, e ku ‘duro 

    Enyin ara, e ku ‘joko 

   Oko ‘gbala wa lode Eko 

   Lodo orimolade.

Egbe: Lodo Baba...


11. Olorun to gbo t'Elijah 

    T'o so mu lo sodo Re 

   Ko wa ran Mosisi lowo 

   Ko le wa d’odo Re.

Egbe: Lodo Baba...


12. Olorun Abraham

    Isaac ati Jakobu 

    Baba, Omo, Emi Mimo 

    Metalokan aiyeraiye.

Egbe: Lodo Baba...


13. Adaba orun, sokale 

    E wa ran baba lowo 

    K‘ade ogo le je tire 

    Ti enikan ko le gba.

Egbe: Lodo Baba...


14. Michael Gabrieli, 

    Enyin agba Angeli 

    Emmanueli Oba wa 

    Metalokan la o sin.

Egbe: Lodo Baba...


15. A f’ope f'Olorun Baba

   Omo at'Emi Mimo 

   Metalokan aiyeraiye 

   Ninu Egbe Serafu.

Egbe: Lodo Baba Aladura 

     Eni to d'egbe yi sile 

     Nibi Serafu, Kerubu 

     Nyin Baba Mimo logo. Amin

English »

Update Hymn