HYMN 739

(FE 765)
“Se giri, ki o si mu aiye le” - Josh.1:6
Tune: Ha Egbe mi, e w’asia1. HA! kerubu, e se giri

   E ma jafara

   Esu ngbongun l'osan, l'oru 

   O nse lasan ni.

Egbe: Kerubu ati Serafu

      E damure nyin

      Ka le doju ‘ja ko esu 

      Ati ogun re.


2. Ha! Serafu, e se giri 

   E ma so‘ra nu

   E ma f’aye sile f‘esu

   N’ijakadi nyin.

Egbe: Kerubu...


3. Enyin Egbe Aladura

   Ninu Egbe yi

   K'Olorun Olodumare

   Ma je k'o re nyin.

Egbe: Kerubu...


4. Enyin Om‘Egbe Akorin 

   E t’ohun nyin se

   A o korin Halleluyah 

   Pel' awon t'orun.

Egbe: Kerubu...


5. Gbogbo Egbe, e ho, e yo 

   E tesiwaju

   A o segun gbogbo ota, 

   Ni oruko Re. 

Egbe: Kerubu...


6. Ogo ni fun Baba loke 

   Ogo ni f’Omo

   Ogo ni fun Emi-Mimo 

   Lai ati lailai.

Egbe: Kerubu ati Serafu

      E damure nyin

      Ka le doju ‘ja ko esu 

      Ati ogun re. Amin

English »

Update Hymn