HYMN 74

H.C. 418 D.C.M (FE 91)
“Awon Angeli si yi ite na ka" - lfi. 7:111. BABA niwaju ite Re,

   L'Angeli nteriba,

   Nigbagbo niwaju Re,

   Ni nwon nkorin iyin,

   Nwon si nfi ade wura won,

   Lele y’ite na ka

   Nwon nfi ohun pelu duru,

   Korin si Oluwa.


2. Didan osumare si ntan

   Si ara iye won,

   Bi Seraf ti nke si Seraf’

   Ti nwon korin ‘yin Re.

   Bi a ti kunle nihinyi,

   Ran ore Re si wa,

   Ka mo pe ‘Wo wa nitosi

   Lati da wa l'ohun.


3. Nihin nibit'awon Angeli

   Nwo wa, ba ti nsin O,

   Ko wa k'a wa ile orun,

   K'a sin O bi ti won

   K’a ba won ko orin iyin,

   K'a ba won mo ‘fe Re,

   Titi agbara y'o fi di

   Tire, Tire nikan. Amin

English »

Update Hymn