HYMN 741

C.M.S 131 H.C 131 6s. 4s (FE 767)
“Olorun si wipe, jeki imole ki o 
wa imole si wa" - Gen. 1:31. lWO ti okunkun 

   Gb’oro agbara re 

   T’o si fo lo

   Gbo tiwa a mbe O 

   Nibit’ ihinrere

   Ko ti tan mole Re 

   K’imole wa.


2. ‘Wo t’iye apa Re 

   Mu iriran w‘aiye

   At‘ilera

   Ilera ti inu

   Iriran gbogbo enia 

   K'imole wa.


3. Iwo Emi oto

   Ti o f’iye fun wa

   Fo kakiri

   Gbe fitila anu

   Fo ka oju omi 

   Nibi okunkun nla 

   K’imole wa.


4. Metalokan Mimo 

   Ogbon, lfe, Ipa 

   Alabukun! 

   B’igbi omi okun 

   Ti nyi ni ipa re

   Be ka gbogbo aiye 

   K’imole wa. Amin

English »

Update Hymn