HYMN 743

t.H.C 511 8 6 6 6 (FE 769) 
“Nwon fi aho, ola ope ati iyin fun
eniti o joko lori ite" - Ifi. 4:9 
Tune: Yika ori te Olorun1. KERUBU ati Serafu 

   Nwon yi ‘te Baba ka 

   Nigbakugba niwaju Re

   Ni nwon nkorin ogo 

Egbe: Nkorin Ogo, Ogo, Ogo

     Nkorin Ogo, Ogo, Ogo.


2. Gbogb' omo Egbe Kerubu 

   E toju iwa nyin

   Gbogbo Egbe t’o wa l’aiye 

   Ni ‘dapo mo t’orun.

Egbe: Nkorin Ogo...


3. Gbogb' omo Egbe Serafu 

   E toju iwa nyin

   K’a ba le pel’awon t’orun 

   Lati ma juba Re.

Egbe: Nkorin Ogo...


4. Awon egbe t’o wa l’orun 

   Nwon wo bi a ti nja

   Nwon si nfi ohun kan wipe 

   E ma te siwaju.

Egbe: Nkorin Ogo...


5. Ninu iponju at’egun 

   Ninu ‘rukerudo 

   Ninu irumi at’iji 

   Yio s’ona wa fefe.

Egbe: Nkorin Ogo...


6. Majemu ati eje Re 

   Ni igbekeke wa 

   B’ileri na tile fale 

   Sugbon ko le pe de.

Egbe: Nkorin Ogo...


7. Nigbat’ a ba par’ise wa 

   Ni aiye osi yi

   Ade Ogo yio je tiwa 

   T’enikan ko le gba.

Egbe: Nkorin Ogo...


8. Ogo, ola at’agbara

   Ni fun Metalokan, 

   Aiyeraiye Olorun wa 

   Amin, beni ki o ri.

Egbe: Nkorin Ogo, Ogo, Ogo

     Nkorin Ogo, Ogo, Ogo. Amin

English »

Update Hymn