HYMN 745

(FE 773) 
“Awon ti si ti yan tele, awon li
o si ti pe" - Rom.8:30
Tune: Oluwa Fise Ran Mi Alleluya1. NINU egbe Mimo yi, ti

   Moses gbe kale

   L’Oluwa s'awon Tire ni ayanfe

   Araiye le ma kegan, araiye le ma sata,

   Sugbon Serafu mo eniti nwon nsin.

Egbe: Egbe na, egbe na,

     Ta fi ran Moses

     Orimolade,

     Ta fi ife se 'pile

     K’ enikeni fese le, 

     K’ibukun aiyeraiye Ie je tiwa.


2. O yan Baba ‘ladura lati 

   j’Oluropo re,

   Nigbati ipe de lati mu re ‘le 

   O yan awon Aposteli lati 

   gberin egbe na,

   Ki nwon mura lati tan ‘hin 

   na kale. 

Egbe: Egbe na, egbe na...


3. Bi nwon ti je oloye ki 

   nwon je onirele,

   Lati tele ‘pase Jesu Oluwa 

   Ka le se won l'asepe bi 

   Aposteli ‘gbani,

   Ti adura won je amu‐bi-ina.

Egbe: Egbe na, egbe na...


4. Gbogbo obinrin oloye, 

   Mary, Martha, Esther,

   Ni eto enyin oloye meteta, 

   E mura giri s'ise bi awon ti igbani,

   Nwon ko ya awon Apostili lese kan. 

Egbe: Egbe na, egbe na...


5. Ki Ore-Ofe Jesu Kristi wa lori papo

   Ko si ba wa gbe lai ati lailai, 

   Mary, Martha, Esta, ‘ti

   Baba nla mejila.

Egbe: Egbe na, egbe na,

     Ta fi ran Moses

     Orimolade,

     Ta fi ife se 'pile

     K’ enikeni fese le, 

     K’ibukun aiyeraiye Ie je tiwa. Amin

English »

Update Hymn