HYMN 746

t.S 65 P.M (FE 774)
“E fi ope fun Oluwa, nitoriti O seun, 
nitoriti anu Re duro laiIai" - Ps.107:1
Tune: “Ojo Nla Lojo Ti Mo Yan.”1. OJO nla l‘ojo t’Oluwa 

   Da egbe Serafu sile

   O ye ki awa ko ma yo

   Fun ‘fe t‘Olorun ni si wa. 

Egbe: Ojo nla l’ojo na,

     T’Olorun d‘egbe yi sile

     O nko wa ka ma gbadura, 

     K’a n’ife si enikeni

     Ojo nla I’ojo na

     T'Olorun d’egbe yi sile.


2. Gbogbo aiye, e ba wa yo 

   Fun ‘fe t’Olorun ni f’aiye

   Enyin ta pe si egbe yi

   E fi ayo korin soke 

Egbe: Ojo nla l’ojo na...


3. Ki kerubu fe Serafu, 

   Ki Serafu fe Kerubu

   O ye k’awa ko ma yo

   Fun ‘fe t’Olorun ni si wa.

Egbe: Ojo nla l’ojo na,

     T’Olorun d‘egbe yi sile

     O nko wa ka ma gbadura, 

     K’a n’ife si enikeni

     Ojo nla I’ojo na

     T'Olorun d’egbe yi sile. Amin

English »

Update Hymn