HYMN 748

C.M.S 137 H.C 124 P.M (FE 776) 
“E wi larin awon keferi pe Oluwa 
li Oba" - Ps. 96:101. WI jade larin keferi p’Oluwa I’Oba

   Wi jade! Wi jade

   Wi jade f'orile-ede

   mu ki nwon korin

   Wi jade! Wi jade!

   Wi jade tiyintiyin pe On 

   o ma po si.

   Pe, Oba nla Ologo l‘oba alafia 

   Wi jade tayotayo bi iji tile nja 

   Pe o joko lor’isan omi

   Oba wa titi lai.


2. Wi jade larin keferi pe, Jesu njoba

   Wi jade! Wi jade!

   Wi jade f'orile-ede, mu k’ide won ja

   Wi jade! Wi jade!

   Wi jade fun awon ti nsokun 

   pe Jesu ye

   Wi jade f’elese pe, O wa lati gbala 

   Wi jade fun awon ti nku pa,

   O ti segun iku.


3. Wi jade larin Keferi, Krist’ njoba l’oke

   Wi jade! Wi jade!

   Wi jade fun keferi, ife n’ijoba Re, 

   Wi jade! Wi jade!

   Wi jade lona opopo l’abuja ona 

   Je ko dun jakejado ni gbogbo 

   agbaiye

   B'iro omi pupo ni k’iho ayo wa je

   Titi gbohun gbohun y’o fi gbe 

   iro na de ‘kangun aiye. Amin

English »

Update Hymn