HYMN 75

H.C. 255 C.M. (FE 92)
"Ogo Oluwa si kun ile Olorun"
- II Kron. 5:141. EMI Orun gb'adura wa,

   Wa gbe 'nu ile yi,

   Sokale pel'agbara Re,

   Wa Emi Mimo wa.


2. Wa bi 'imole si fi han wa,

   B'aini wa ti po to,

   Wa to wa si ona lye,

   Ti Olododo nrin.


3. Wa bi ina ebo Mimo

   S'okan wa di mimo,

   Je ki okan wa je ore

   F'oruko Oluwa.


4. Wa bi iri si wa bukun

   Akoko mimo yi,

   Ki okan alaileso wa,

   Le yo l'agbara Re.


5. Wa bi adaba n'apa Re,

   Apa ife Mimo,

   Wa je ki Egbe yi l'aiye,

   Dabi Egbe t‘orun.


6. Emi orun gb’adura wa,

   S'aiye yi d'ile Re,

    Sokale pel'agbara e,

    Wa, Emi Mimo wa. Amin

English »

Update Hymn