HYMN 752

t.S. 43 P.M (FE 786) 
“Emi yio si pada to Olorun Io" - Oni.12:7
Tune: IpileTi Jesu fi lele1. ADORIN odun ni ye odun wa 

   Bi ojo alagbase

   A o ke wa lule bi itanna eweko 

   Awa a si koja lo.

Egbe: O digbose (arakunrin tabi arabinrin)

     O digbose, (Arakunrin tabi arabinrin)

     O d’ojo ajinde.


2. Koriko, b'o ku ko tun le ye mo 
 
   Iwo ku lati tun ye

   Ade ti ki sa yio je tire

   Lodo Olugbala.

Egbe: O digbose...


3. Losu to koja, t’awa tire ni 

   Loni ipo re s'ofo

   (Arakunrin, Arabinrin)

   wa ko lo s’idale.

Egbe: O digbose...


4. Je ki eyi je eko fun gbogbo wa,

   Lati tun wa wa se

   lgi gbigbe le wa ni iduro

   K‘a ke tutu lule.

Egbe: O digbose...


5. Iwa wa laiye yio jeri si wa 

   Bi ‘gbehin y‘o tori

   Rere (Arakunrin, Arabinrin) 

   ti nto lehin 

   O ti se won to le se.

Egbe: O digbose...


6. Egbe at’Ebi (Arakunrin, Arabinrin) wa

   A ba nyin daro lokan 

  Ireti mbe a o pade loke 

  Ni ojo Ajinde wa.

Egbe: O digbose (arakunrin tabi arabinrin)

     O digbose, (Arakunrin tabi arabinrin)

     O d’ojo ajinde. Amin

English »

Update Hymn