HYMN 758

H.C 545 L.M (FE 792)
“On o wo inu alafia” - Isa. 57:21. IGBA asale ti dun to

   Ti ara tu ohun gbogbo 

   Gbat’ itansan orun ale

   Ba ntanmole s’ohun gbogbo.


2. Beni ‘kehin onigbagbo 

   On a simi l’alafia 

   Igbagbo t’o gbona janjan 

   A mole ninu okan re.


3. Imole kan mo loju re

   Erin si bo ni enu re

   On f’ede t’ahon wa ko mo 

   Soro ogo t’o sunmole.


4. Itansan ‘mole t’orun wa 

   Lati gba niyanju lona 

   Awon angeli duro yika 

   Lati gbe lo s’ibugbe won.


5. Oluwa, jek’a lo bayi

   K’a ba O yo, k’a r’oju Re

   Te aworan Re s’okan wa 

   Si ko wa b’a ti ba O rin. Amin

English »

Update Hymn