HYMN 759

H. C 544 7.7.7.7.8.8 (FE 793)
“Ki emi ki o to lo kuro nihinyi, ati ki 
emi ki o to se alaisi” - Ps. 39:131. LALA alagbase, tan; 

   Ojo ogun ti pari;

   L’ebute jijin rere,

   Ni oko re ti gun si. 

Egbe: Baba, Iabe itoju Re,

     L‘awa f’iranse Re yi si.


2. Nibe l’a re won l’ekun 

   Nibe, nwon m’ohun gbogbo

   Nibe l’onidaj’ oto 

   Ndan ise aiye won wo.

Egbe: Baba, Iabe...


3. Nibe l’olus’agutan 

   Nko awon agutan lo,

   Nibe l’o ndabobo won, 

   Koriko ko le de ‘be.

Egbe: Baba, Iabe...


4. Nibe l’awon elese

   Ti nteju m’agbelebu,
  
   Y’o mo ife Kristi tan 

   L’ese Re ni Paradise.

Egbe: Baba, Iabe...


5. Nibe l'agbara Esu,

   Ko le b’ayo won je mo

   Krist Jesu sa nso won;

   On t’o ku dande won. 

Egbe: Baba, Iabe...


6. ‘Erupe fun erupe 

   L’ede wa nisisi 

   A te sile lati sun 

  Titi d’ojo ajinde.

Egbe: Baba, Iabe itoju Re,

     L‘awa f’iranse Re yi si. Amin

English »

Update Hymn