HYMN 76

H.C. 259. 7.7.7 (FE 93)
"Iwo ra Emi Re jade, a si da won"
- Ps. 104:301. WA, Parakliti Mimo,

   Lat'ibugbe Re, Orun,

   Ran itansan 'mole wa.


2. Baba talaka, wa ‘hin

   Olufunni l'ebun wa,

   lmole okan jo wa.


3. Baba Olutunu wa

   Alejo toro f 'okan,

   Pelu itura-Re wa.


4. ‘Wo n‘isimi n'nu lala

   lboji ninu orun,

   ltunu ninu ‘ponju.


5. ‘Wo ‘mole t’o mo gara

   Tan sinu aiya awon;

   Enia Re oloto.


6. L’aisi Re kil’eda je?

   lse at‘ero Mimo,

   Lat’odo Re wa ni won.


7. Eleri, so di mimo,

   Agbogbe masai wo san,

  Alaileso mu s’eso.


8. Mu okan tutu gbona

   M‘alagidi teriba,

   Fa asako wa jeje.


9. F’emi ‘jinle Re meje,

   Kun awon oloto Re,

   F’agbara Re s’abo won.


10. Ran or’ofe Re sihin,

    Ekun igbala laiye,

    At’alafia l’orun. Amin

English »

Update Hymn