HYMN 760

(FE 794)
"Bo sinu aya Oluwa re" - Matt 25:211. OLUFE, ma sun, ko si ma simi, 

   Gb‘ ori le aiya Olugbala Re

   A fe o, sugbon Jesu fe o ju, 

   Sunre, Sunre, Sunre.


2. Orun itura bi omo titun 

   lse on ekun re ti pari na 

   Simi l'alafia titi aiye 

   Sunre, Sunre, Sunre.


3. Simi titi aiye ki yio si mo, 

   Ti ao ko Alikama s‘aba, 

   Ti ao sun epo on iyangbo, 

   Sunre, Sunre, Sunre.


4. Titi ogo ajinde yio ti tan

   Tit’ awon to ku n’nu Jesu yio nde; 

   On yio si wa pelu olanla Re, 

   Sunre. Sunre, Sunre.


5. A o f’ ife Jesu se o logo, 

  Wo yio si ji laworan Olorun, 

  On yio si mu ade ogo re wa, 

  Sunre, Sunre, Sunre.


6. Sunre, Olufe, ki se titi lai, 

   Lehin ‘gba die awon eni mimo 

   Yio ma gbe po ni irepo mimo 

   Sunre, Sunre, Sunre.


7. Titi ao fi pade ni ite Re,

   Ao si wo wa l’agbada funfun; 

   T'a o si ri gegeb' a ti mo wa, 

   Sunre, Sunre, Sunre. Amin

English »

Update Hymn