HYMN 763

C.M; .S 485 H.C. 509 P.M (FE 797)
"Agbo kan ati Oluso-Agutan ni yio si je"
- John 10:161. NIHIN l‘awa nje ‘rora 

   Nihin ni a ma pinya 

   L’orun, ko si ‘pinya.

Egbe: A! bi o ti dun to!

     Dun to, dun to, dun to! 

     A! bi o ti dun to,

     Gba t’a ki o pinya mo.


2. Awon t’o feran Jesu 

   Nwon o lo s’oke orun 

   Lo b’awon t’o ti lo.

Egbe: A! bi o ti dun to!...


3. Omode y’o wa nibe 

   T’o wa Olorun l’aiye 

   Ni gbogbo 'le eko.

Egbe: A! bi o ti dun to!...


4. Oluko, baba, iya, 

   Nwon a pade nibe na, 

   Nwon ki o pinya mo.

Egbe: A! bi o ti dun to!...


5. 'Bi a o ti yo po to! 

   Gba t’a ba r’ Olugbala 

   Ni ori ite Re!

Egbe: A! bi o ti dun to!...


6. Nibe l’ao korin ayo 

   Titi aiye ailopin

   L’a o ma yin Jesu.

Egbe: A! bi o ti dun to!

     Dun to, dun to, dun to! 

     A! bi o ti dun to,

     Gba t’a ki o pinya mo. Amin

English »

Update Hymn