HYMN 764

C.M.S 521 C.M (FE 798)
“Isise kan ni mbe larin emi ati iku”
- 1Sam. 20:31. ODUN nyipo, o ji emi 

   T’O ti fi fun wa ri 

   Ibikibi to wu ka wa 

   Isa-oku la nre.


2. Yi ile ka l’ewu duro 

   Ko le ti wa s‘isa 

   Arun buburu si duro 

   Lati le wa lo ‘le.


3. Ayo tab’egbe ailopin 

   Duro de emi wa

   Wo! ba ti nrin laibikita 

   Leti bebe iku.


4. Oluwa, ji wa l’orun wa 

   K’a r’ona ewu yi 

   Nigbat’ a ba pe okan wa 

   K’a ba O gbe titi. Amin

English »

Update Hymn