HYMN 767

C.M.S 558 Alford D. 7.6.8. 6 (FE 80)
"A won ni aso funfun" - Ifi. 7:91. EGBEGBERUN aimoye 

   Nwon wo aso ala 

   Ogun awon t'a rapada 

   Nwon kun ‘bi mole na 

   Ija won pelu ese 

   At‘iku ti pari

   E si ‘lekun wura sile 

   Fun awon asegun.


2. Iro Halleluya won

   L'o gb'aiye orun kan 

   Iro egbegberun Harpu 

   Ndun pe ‘segun de tan 

   Ojo t'a s’eda aiye

   T’a da oril’ede

   Ayo nla pa ‘banuje re 

   Ti a fun ni kikun.


3. A! ayo t’a ko le so 

   L’eti bebe Kenaan

   Idapo nla wo lo to yi 

   Ibi t’a ki pinya

   Oju t'o kun f’ekun ri 

   Y’o tu mo‘le ayo

   Ki yio si alaini baba 

   Opo ki yio si mo.


4. Mu igbala nla Re wa 

   Od’agutan t’a pa

   So ‘ye awon ayanfe Re 

   Mu ‘pa Re k’o joba 

   Wa, ife oril'ede

   Da onde Re sile

   Wa fi ami' leri Re han 

   Wa, Olugbala wa. Amin

English »

Update Hymn