HYMN 769

C.M.S 529 H.C 397 7s 6s (FE 803)
"Krist ni Ori Ijo énia Re" - Efe 5:23
Tune: Duro Duro fun Jesu1. JESU Oluwa ni‘se 

   lpile Ijo re

   Omi ati oro Re 

   Ni On si fi tun da

   O t’orun wa, O fi se 

   Iyawo mimo Re 

   Eje Re l'O si fi ra

   Ti O si ku fun u.


2. N'ile gbogbo l’a sa won 

   Sugbon nwon je okan 

   Oluwa kan, gbagbo kan 

   Ati baptisi kan

   Oruko kan ni nwon nyin 

   Onje kan ni nwon nje 

   Opin kan ni nwon nlepa 

   Nipa ore-ofe.


3. Bi aiye tile nkegan 

   Gbat’ iyonu de ba 

   Bi ‘ja on eko‐ke-ko

   Ba mu iyapa wa

   Awon mimo yio ma ke 

   Wipe ‘yo ti pe to? 

   Oru ekun fere di

   Oro orin ayo.


4. L‘arin gbogbo 'banuje 

   At'iyonu aiye

  O nreti ojo kehin 

   Alafia lailai

   Titi y'o f’oju re ri 

   Iran ologo na

   Ti ijo nla asegun 

   Y'o d‘ijo ti nsimi.


5. L'aiye, yi ni 'dapo

   Pelu Metalokan

   O si ni ‘dapo didun 

   Pel'awon t‘o ti sun

   A! alabukun mimo

  Oluwa, fi fun wa

   Ka ba le ri bi awon

   Ka ba O gbe ‘lorun. Amin

English »

Update Hymn