HYMN 773

C.M.S 527 H.C 388 6s (FE 307)
“Oluwa mo fe fe bugbe ile Re”
- Ps. 26:81. OLORUN, awa fe 

   Ile t’ola Re wa 

   Ayo ibugbe Re 

   Ju gbogbo ayo lo.


2. Ile adura ni

   Fun awa omo Re 

   Jesu, O wa nibe 

   Lati gbo ebe wa.


3. Awa fe ase Re 

  Kil’o dun to laiye 

  Nib’awon oloto 

  Nri O nitosi won.


4. Awa fe oro Re 

   oro Alafia 

   Tinunu at’iye 

   Oro ayo titi.


5. A fe korin anu

   T’a nri gba l’aiye yi 

   Sugbon awa fe mo

   Orin ayo t'orun.


6. Jesu, Oluwa wa

   Busi fe wa nihin

   Mu wa de ‘nu ogo 

   Lati yin O titi. Amin

English »

Update Hymn