HYMN 774

8.6.8.6.8.8.8.61. E wa k’a jo jumo korin 

   Ife ni Olorun

   Orun, aye mu yin won wa 

   Ife ni Olorun

   Ki gbogbo okan ji kuro 

   Ninu ese ki won f’ayo 

   Korin didun n’tori Jesu 

   lfe ni Olorun.


2. E so ni gbogbo agbaye 

   Ife ni Olorun

   N’nu Krist’ l’ekun ‘rapada wa 

   Ife ni Olorun

   Eje Re le w’ese wa nu

   Emi Re s’oru wa d’osan

   O nto ‘kan wa lati so pe 

   Ife ni Olorun.


3. Ayo ni ipin wa nihin 

   Ife ni Olorun

   Okan wa nyo si ‘leri Re 

   Ife ni Olorun

   Orun at’ abo wa losan

   O si mba wa gbe ni oru 

   On yo wa pelu wa titi 

   Ife ni Olorun.


4. Ni Sion Iao tun korin yi 

   Ife ni Olorun

   Orin t’o ga soke julo 

   Ife ni Olorun

   Titi aye aninipekun 

   Pelu awon mimo loke 

   Orin wa to dun julo ni 

   Ife ni Olorun. Amin

English »

Update Hymn