HYMN 777

(FE 811) 8s7s
"O si wi fun u pe, Emi ni Jehovah"
- Ex.6:2
Tune: Ma toju mi Jihofa Nla1. JESU Olori Egbe wa, 

   Bukun wa k‘awa to lo 

   Baba Olorisun gbogbo 

   Je ka ri O larin wa.

Egbe: Jah Jehovah! Jah Jehovah!

      Kabiyesi Oba wa - 6x


2. Jowo Jesu awa mbe O,

   K‘a ma ri agbako aiye

   K ari 'se se, k‘oja k’o ta, 

   K‘omo Re ma rahun mo.

Egbe: Jah Jehovah!...


3. Sure fun wa l‘ojo aiye wa, 

   K‘ebi ale ma pa wa, 

   K’enikeni mase rahun 

   M’ese Egbe wa duro.

Egbe: Jah Jehovah!...


4. Ma je ki fitila re ku, 

   Larin Egbe Serafu 

   Gege bi Serafu t’orun 

   Ki gbogbo wa jo yin O.

Egbe: Jah Jehovah!...


5. Rant’ egbe t’o wa l’okere 

   Fun won l'okun ilera

   Aje, oso ko ma ri won, 

  Iwo lo ns’Alabo won.

Egbe: Jah Jehovah!...


6. Jehovah Jireh Oba wa, 

   Jehovah Nissi Baba

   Johovah Shalom,

   S’amona wa lojo ‘ku.

Egbe: Jah Jehovah! Jah Jehovah!

      Kabiyesi Oba wa - 6x Amin

English »

Update Hymn