HYMN 779

C.M.S 548 10s (FE 813)
"Oluwa k’o fi alafia busi fun
awon enia Re" - Ps.29:111. OLUGBALA, a tun fe f’ohun kan 

   Yin Oruko Re ka to lo si le 

   N’ipari isin, a ntor’anu Re

   Ao si kunle fun ibukun Re.


2. F’alafia fun wa ba ti nrele 

   Je ka pari ojo yi pelu Re 

   Pa aiya wa mo, si so ete wa 

   T’a fi npe oruko re nihin yi.


3. F’alafia fun wa loru oni 

   So okunkun re di imole fun wa 

   Ninu ewu yo awa omo Re 

   Okun on ‘mole j'okanna fun O.


4. F’alafia fun wa loj’aiye wa

   Re wa lekun, ko si gbe wa nija 

   Gbati’ O ba si f’opin si idamu wa 

   Pe wa, Baba, s’orun Alafia. Amin

English »

Update Hymn