HYMN 780

(FE 814)
"Ma beru nitori emi wa pelu re"
- Isa. 43:51. OLORUN wa mbe larin wa, 

   Y‘o si bukun gbogbo wa, 

  Wo oju orun b‘o li su

  Yio rojo ibukun.

Egbe: K'o de, Oluwa, a be O

     Je k'ojo ibukun de,

     Awa nduro, awa nduro, 

     M'okan gbogbo wa soji.


2. Olorun wa mbe larin wa, 

   Ninu ile mimo yi; 

   Sugbon a nfe ‘tura okan 

   Ati opo ore-ofe.

Egbe: K'o de, Oluwa...


3. Olorun wa mbe larin wa; 

   K‘a f'okan 'gbagbo bere 

   Ohun t‘a fe lowo Re, ki 

   ‘Fe Re m’okan wa gbona.

Egbe: K'o de, Oluwa...


4. Olugbala gb‘adura wa,

   B'a ti f‘igbagbo kunle

   Jo si ferese anu Re

   K’o da ‘bukun sori wa.

Egbe: K'o de, Oluwa, a be O

     Je k'ojo ibukun de,

     Awa nduro, awa nduro, 

     M'okan gbogbo wa soji. Amin

English »

Update Hymn