HYMN 781

(FE 815)
“Okan mi yio sure fun O" - Gen. 27:41. SURE fun wa loni, Baba wa orun 

   A gboju wa soke si O,

  We to sure f’Abraham

   baba wa,

   Jowo sure fun wa.

Egbe: Alpha ati Omega

     A si okan wa paya fun O, 

     Ma je ka lo Iofo.


2. Metalokan Mimo Alagbara 

   lfe to jinle julo

   Awamaridi Olodumare 

   Jo f'ire kari wa.

Egbe: Alpha ati Omega...


3. Awa nke pe O loni, Baba wa, 

   Ma je k’omo Re rahun

   Ko sohun ti jamo lehin ekun 

   Jowo dabobo wa.

Egbe: Alpha ati Omega...


4. Wo lo m'omi lat’inu apata 

   F’awon enia Re saju

   O rojo manna pelu lat’orun 

   Jowo pese fun wa.

Egbe: Alpha ati Omega

     A si okan wa paya fun O, 

     Ma je ka lo Iofo. Amin

English »

Update Hymn