HYMN 783

(FE 817)
"Oba awin oba ati Oluwa awon 
Oluwa" - Ifi. 19:161. E WOLE f'Oba wa 

Omo Mimo Baba 

Eleda, Alabo

Olugbala gbogbo araiye. 

Egbe: Gbogbo aiye, e fori bale

f 'Olodumare

Enit'o ra wa pada

Alleluya gb’orin segun na ga 

Metalokan wa l'Oba ogo.


2. Mi si wa, Oluwa

Ka pin ‘nu ogo Re 

Orisun iye wa 

Ato-bajaiye Oba ogo.

Egbe: Gbogbo aiye...


3. Aiye pel’ekun re

Tire ni Oluwa

Awon to gba O gbo

Ni yio jogun Re titi aiye.

Egbe: Gbogbo aiye...


4.  lkore aiye gbo

   E mura, araiye 

   Olukore fere de 

   Alikama nikan ni Tire.

Egbe: Gbogbo aiye...


5. Lojo ifarahan

   Jewo mi, Oluwa

   Jek‘ore-ofe Re

   Mu wa ye lati ba O gunwa.

Egbe: Gbogbo aiye, e fori bale

      f 'Olodumare

      Enit'o ra wa pada

      Alleluya gb’orin segun na ga 

      Metalokan wa l'Oba ogo. Amin

English »

Update Hymn