HYMN 784

8.7.8.7 D
Tune: ’Tori mi ati ’hinrere1. Mo I‘Ore kan, ife Re po 

   O fe k‘emi t‘o m‘O

   Okun ife I'O fi fa mi

   O si de mi mo ‘ra Re 

   Koko ‘fe re, t‘a ko le tu 

   Lo mo okan mi sibe 

   Mo je Tire, On je temi 

   Lae ati titi laelae.


2. Mo l‘Ore kan, ife Re po 

   O ku lati gba mi la

   lye nikan ko l‘o fun mi 

   O fi ara Re ji mi

   Nko ni p‘ohun kan ni temi 

   Un o pamo f'Olufunni 

   Okan, agbara, emi mi 

   Tire, ni titi laelae.


3. Mo l‘Ore kan, ife Re po 

   Gbogb’agbara l'a fi fun 

   K'O le so mi li ajo mi 

   K‘O si mu mi de orun 

   Ogo ailopin ntan ‘mole

   Lati fun mi li okun

   Un o sora, un o sise, un o ja 

   Lehin na, un o simi lae.


4. Mo I‘Ore kan, ife Re po 

   Oniyonu, Oloto 

   Olugbimo at‘Amona 

   Alabo t'o lagbara

   Kini ‘ba le ya mi lodo

   Eni fe mi po to yi

  lye‘ Iku? aye, egbe

  Beko, Mo je Tire lae. Amin

English »

Update Hymn