HYMN 785

C.M.S 139 H.C 136 C.M (FE 819)
"Emi o si fi ota sarin iwo ati obinrin na 
ati iru omo re ati omo re, on o fo o li ori 
iwo o si pa a ni gigisi." - Gen. 3:151. lYlN f‘Eni Mimo julo 

   Loke ati n'ile 

   Oro Re gbogbo je ‘yanu 

   Gbogb‘ ona Re daju.


2. Ogbon Olorun ti po to! 

   ‘Gbat’enia subu

   Adam keji wa s’oju ja 

   Ati lati gbala.


3. Ogbon ife! p‘eran ara 

   T‘o gbe Adam subu 

  Tun b‘ota ja ija otun 

  K‘o ja k‘o si segun.


4. Ati p’ebun t'o f’or-ofe 

   So ara di otun

   Olorun papa Tikare 

   J'Olorun ninu wa.


5. Ife ‘yanu! ti Eniti 

   O pa ota enia

   Ninu awo awa enia 

   Je irora f’enia.


6. Nikoko ninu ogba ni 

   Ati l’ori igi

   T’o si ko wa lati jiya 

   To ko wa lati ku.


7. Iyin f’Eni Mimo julo

   L'oke ati n’ife 

   Oro Re gbogbo je ‘yanu 

   Gbogb’ ona Re daju. Amin

English »

Update Hymn