HYMN 786

(FE 820)
"Awon ti o gba ti Olorun gbo nwon
o ri iye ainipekun”
Tune: Jesu Mo wa Sodo Re1. A DUPE lowo Olorun 

   T'O fi Jesu kristi fun wa, 

   Lati ra raiye pada

   Lowo ese ati esu.

Egbe: E yin logo, e f'ope fun 

     Olorun Metalokan 

     Fun anu at'ore Re

     Lori gbogbo Egbe Serafu.


2. Agbara Olorun ndagba 

   Ogo Jesu nhan si wa 

   Agbara Emi Mimo wa, 

   Larin Egbe Serafu.

Egbe: E yin logo...


3. Gbogbo enia at’orile-ede 

   Dorikodo s‘adura

   E yipada l’emi oto

   Ki Baba orun gba wa. 

Egbe: E yin logo...


4. Ese po, aiye yi daru

   Esu njale, o si nyo 

   K’onigbagbo pe adura po 

   K’a Ie segun ese at‘esu.

Egbe: E yin logo...


5. Olufokansin onigbagbo 

   Jesu mo ise ikoko re

   Mase lo, l’ohun Oluwa nwi 

   Oluko re nsunmole.

Egbe: E yin logo...


6. Kerubu, Serafu, mura 

   Alufa, Bishop, mura 

   Enyin to mo Jesu, e mura 

   Lojo kehin ojo dajo.

Egbe: E yin logo...


7. Ajodun miran l’awa nse 

   T’Olorun ran Moses 

   Lati s’egbe yi loruko 

   Ogun orun Serafu.

Egbe: E yin logo...


8. Egbe Mose, e mura dide 

   Larin egbe Kerubu, Serafu 

   Olorun Baba lo fun wa 

   Gbe asia re soke.

Egbe: E yin logo...


9. Keferi, Imale, ewa 

   Onigbagbo, e ma kalo 

   Ka jo yin Olorun logo 

   Ka le gba ade iye.

Egbe: E yin logo...


10. Olorun Baba sanu wa 

    Dariji wa, pa wa mo 

    Ran wa lowo, gbadura wa 

    Titi aiye ainipekun.

Egbe: E yin logo, e f'ope fun 

     Olorun Metalokan 

     Fun anu at'ore Re

     Lori gbogbo Egbe Serafu. Amin

English »

Update Hymn