HYMN 787

(FE 821)
“Yin I gegebi titobi re“ - Ps.150:2
Tune: Oluwa fise ra mi Alleluya1. E BA wa korin iyin Halleluya 

   E ba wa yin Oba Ogo,

   To da wa si di oni

   Halleluyah!

   E ba yin Oba Ogo.

Egbe: Bus’ayo, arakunrin 

      E gbe orin iyin 'ga, 

      Bu s’ayo, arabinrin, 

      Halleluya!

      E wa gbe Ebenezer ro.


2. E ba wa korin iyin

   Halleluya

   Fun isegun t’O fi fun wa,

   Ti ko jek’ota yo wa Halleluya 

   E ba wa yin Oba Ogo.

Egbe: Bu s’ayo... 


3. E ba wa korin iyin,

   Halleluyah

   Fun ‘se ‘yanu to se larin wa, 

   To fo itegun Esu, Halleluya! 

   T’o mu wa la ‘danwo koja.

Egbe: Bu s’ayo... 


4. E ba wa korin iyin, 

   Halleluya!

   Fun idagbasoke emi wa, 

   To pe wa sinu agbo, 

   Halleluya!

   Ti ko je ka d’eni gbajare.

Egbe: Bu s’ayo... 


5. Iyin f’Olorun Baba 

   Halleluya!

   Iyin fun Olorun Omo, 

   Iyin fun Emi Mimo Halleluya!

   Metalokan la fi ‘yin fun.

Egbe: Bus’ayo, arakunrin 

      E gbe orin iyin 'ga, 

      Bu s’ayo, arabinrin, 

      Halleluya!

      E wa gbe Ebenezer ro. Amin

English »

Update Hymn