HYMN 792

(FE 826)
"Oluwa fun ni, Oluwa si gba Io"
 - Job.1:21
Tune: Jesu ni Balogun Oko1. EMI o ha lo lowo ofo? 

   Lati b‘Oba Olorun mi 

   K’a ma jiya laiye yi tan 

   K’a tun jiya ni orun.

Egbe: Jesu npe agbaiye, e wa 

     Lati gba 'gbala I‘ofe 

     Ki oko 'gbehin to koja

     Pe, ma bo enyin omo MI.


2. Elese jowo yipada

   Ki oko ‘gbehin to kun

   Ki o ma ba ke abamo

   Ni ojo igbehin yi.

Egbe: Jesu npe agbaiye...


3. Enyin Om-Egbe Serafu

   E mura si ise nyin

   Lati ma kede oro na 

   K’oko ‘gbehin to koja.

Egbe: Jesu npe agbaiye...


4. Enyin Om-Egbe Kerubu

   E damure nyin giri

   E ma j’afara adura

   K’oko gbehin to kun tan.

Egbe: Jesu npe agbaiye...


5. Enyin Egbe Aladura 

   E gbe ‘da segun soke 

   Lati fi ba esu jagun

   Fun Kristi Oba Ogo. 

Egbe: Jesu npe agbaiye...


6. Enyin Asaj’ Egbe Seraf’ 

   E wasu ‘ihinrere Mi

   Ki e ba le gba ‘de Ogo

   Ni ojo igbehin na.

Egbe: Jesu npe agbaiye, e wa 

     Lati gba 'gbala I‘ofe 

     Ki oko 'gbehin to koja

     Pe, ma bo enyin omo MI. Amin

English »

Update Hymn