HYMN 793
Tune: 8s 7s
“Oba ti kii ye majemu”
1.  JESU nikan ni a nwasu 
Jesu nikan l’a n rohin 
Awa yoo gbe Jesu soke 
Oun nikan l‘awa n fe ri.
Egbe: Jesu nikan Jesu nikan 
Jesu nikan l’orin wa 
Olugbala, Oluwosan
Oba ti n bo leekeji.
2.  Jesu ni Olugbala wa,
O ru gbogbo ebi wa 
Ododo Re l‘O gbe wo wa 
O n s' agbara wa d’otun.
Egbe: Jesu nikan...
3.  Jesu l’o n so wa di mimo 
T'o n we abawon wa nu 
O n segun ese at’ara 
Nipa iranwo Emi.
Egbe: Jesu nikan...
4.  Jesu ni Oluwosan wa 
O ti ru ailera wa 
Nip’agbara ajinde Re 
A ni ilera pipe.
Egbe: Jesu nikan...
5.  Jesu nikan l’agbara wa 
     Agbara Pentikosti
     Joo, da agbara yii iu wa 
     F’Emi Mimo Re kun wa.
Egbe: Jesu nikan...
6.  Jesu ni awa n duro de
     A n reti ohun ipe 
     ‘Gba t'O ba de Jesu nikan 
     Yoo je orin wa titi.
Egbe: Jesu nikan Jesu nikan 
          Jesu nikan l’orin wa 
          Olugbala, Oluwosan
          Oba ti n bo leekeji.  Amin
English »Update Hymn