HYMN 796

H.C 216 S.M (FE 830)
"Yio si dabi imole oro nigbati orun ba la
ati oro ti ko ni ikuku” - 2Sam. 23:4

APA 11. OJO ‘mole l’eyi

Ki ‘mole wa l’oni 

Wo Orun, ran s’okunkun wa, 

K’o si le oru lo.


2. Ojo simi l’eyi 

S’agbara wa d‘otun 

S'ori aibale aiya wa 

Seri itura Re.


3. Ojo alafia

F’alafia fun wa

Da iyapa gbogbo duro 

Si mu ija kuro.


4. Ojo adura ni

K’aiye sunmo Orun 

Gb’okan soke si odo Re 

Si pade wa nihin.


5. Oba ojo l’eyi

Fun wa ni isoji

Ji oku okan wa s’ife 

Wo asegun iku. Amin


H.C 219 S.M (FE 831)
“Ojo kan fun adura ninu ile Re, O
san ju egbe run ojo lo" - Ps.94:10 

APA 21. KABO! ojo 'simi

T'o r’ajinde Jesu

Ma bo wa m‘okan yi soji 

Si mu inu mi dun.


2. Oba tikare wa

Bo ljo Re loni 

Nihin l’a wa ti a si ri 

A nyin, a gbadura.


3. Ojo kan f'adura 

N'nu ile mimo Re

O san j'egberun ojo lo 

T'a lo f’adun ese.


4. Okan mi y'o f'ayo 

Wa n‘iru ipo yi

Y'o si ma duro de ojo 

Ibukun ailopin. Amin

English »

Update Hymn