HYMN 798

t.GB 466 (FE 833)
“A wo won ni aso funfun, imo ope
si mbe li owo won” - Ifi.7:9
Tune: “Olorun kan l'o to k’a sin”1. ENYIN ero nibo l’e nlo 

   T‘enyin ti ‘mope,

   lowo nyin?

   Awa nlo pade Oba wa 

  Gegebi ‘leri re si wa.

Egbe: A nlo s’afin, s’afin Oba rere, 

     A nlo s’ile ‘leri, nibiti

     ese ko le de

     Nibiti simi wa lailai.


2. Enyin, ero, e so fun wa 

   T’ayo pipe ti mbe nibe 

   T’aso ala at’ade Ogo

   Ti Jesu y’o fun wa loke.

Egbe: A nlo s’afin...


3. A ko ni ‘bugbe kan nihin 

  O buru bi ‘hin je le wa 

  Ayo l’ogo ekun lale 

  Sugbon eyi ko si loke.

Egbe: A nlo s’afin...


4. Egbe orun, e silekun 

   F’egbe aiye lati wole 

   Awa n’ise at’iponju

   Nwon de lati b’Oluwa gbe.

Egbe: A nlo s’afin...


5. Ogunlogo nibi gbogbo 

   Ti nwon ti segun aiye yi 

   Olorun so won di omo 

   Wa ore mi, ki ile to su.

Egbe: A nlo s’afin...


6. Oja aiye, oja asan 

   B’Oluwa n’oja, k’o jere 

   Ore aiye, ore asan 

   B’Oluwa s’ore, ki idani.

Egbe: A nlo s’afin...


7. Wo! ko tun s’adun laiye mo 

   Ibjae po rere lo

   B’Olowa re, pinnu loni

   Ki ‘gbehin re ba le layo.

Egbe: A nlo s’afin...


8. Agbagba merinlegun 

   Enyin l’awa fe ba k’egbe 

   Tori ko s’adun laiye mo 

   E ka wa ye f’adun loke.

Egbe: A nlo s’afin, s’afin Oba rere, 

     A nlo s’ile ‘leri, nibiti

     ese ko le de

     Nibiti simi wa lailai. Amin

English »

Update Hymn