HYMN 80

C.M.S. 591 S. 165 P.M (FE 97)
“Fe mi, emi o sure to o"
- Orin Solo. 1:41. OLUWA, emi sa ti gbohun Re,

   O nso ife Re si mi,

   Sugbon mo fe nde l’apa igbagbo,

   Ki nle tubo sunmo O.

Egbe: Fa mi mora, mora Oluwa

      Sib'agbelebu t’Oku,

      Fa mi mora, mora, mora Oluwa

      Sib' eje Re t’o n’iye.


2. Ya mi si mimo fun ise Tire,

   Nipa Ore-Ofe Re,

   Je ki nfi okan igbagbo w‘oke

   K’ife mi te si Tire.

Egbe: Fa mi mora...


3. A! ayo mimo ti wakati kan,

   Ti mo lo nib‘ite Re

   ‘Gba mo gbadura si O, Olorun

   Ti a soro bi ore.

Egbe: Fa mi mora...


4. Ijinle ife mbe ti nko le mo

   Titi ngo fi koja odo!

   Ayo giga ti emi ko le so,

   Titi ngo fi de ‘simi.

Egbe: Fa mi mora... Amin

English »

Update Hymn