HYMN 800

C.M.S. 593 S. 81 P.M (FE 835)
“K’Ore-ofe Jesu kristi Oluwa wa
K’o pelu gbogbo nyin” - 1Kor. 16:23
1. ORE-OPE! ohun

   Adun ni l’eti wa, 

  Gbohun-gbohun re y’o 

  gba orun kan, 

  Aiye o gbo pelu.

Egbe: Ore-Ofe sa,

     N’igbekele mi,

     Jesu ku fun araiye,

     O ku fun mi pelu.


2. Ore-Ofe l’o ko

   Oruko mi l'orun

   L'o fi mi fun Od’agutan, 

   T’o gba iya mi je.

Egbe: Ore-Ofe sa...


3. Ore-ofe to mi,

   S’ona alafia;

   O ntoju mi, lojojumo, 

   Ni irin ajo mi.

Egbe: Ore-Ofe sa...


4. Ore-Ofe ko mi, 

   Bi a ti gbadura,

   O pr :ni mo titi d‘oni 

   Ko si jeki nsako.

Egbe: Ore-Ofe sa...


5. Jek' ore-ofe yi, 

   F’agbara f’okan mi;

   Ki nle fi gbogbo ipa mi, 

   At’ojo mi fun O.

Egbe: Ore-Ofe sa,

     N’igbekele mi,

     Jesu ku fun araiye,

     O ku fun mi pelu. Amin

English »

Update Hymn